Kí ni akàn gan-an?
Ara rẹ ń dá sẹ́ẹ̀lì tuntun nígbà gbogbo, ó sì ń dúró nígbà tí ó bá tó. Akàn ni ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀ nígbà tí sẹ́ẹ̀lì kan bá pàdánù àmì ìdúró náà tí ó sì ń ṣe àdàkọ ara rẹ̀ lọ.
Kì í ṣe àìsàn kan ṣoṣo. Akàn tí ó bẹ̀rẹ̀ ní ọmú ń hùwà yàtọ̀ sí akàn tí ó bẹ̀rẹ̀ nínú ẹ̀dọ̀fóró. Ìdí nìyí tí ìtọ́jú rẹ kò ní jọ ti ẹlòmíràn.
Dókítà méjì ló kọ ọ́. A fi wé ìsọfúnni fún aláìsàn láti ọ̀dọ̀ National Cancer Institute ti Amẹ́ríkà àti Cancer Research UK. A túmọ̀ rẹ̀ láti inú káàdì èdè Gẹ̀ẹ́sì. A ń gbèrò kí dókítà tí ó gbọ́ Yorùbá ṣàyẹ̀wò ìtúmọ̀ yìí.