Ẹ sọ ìdá ọgọ́ta. Ìdá ọgọ́ta nínú kí ni?
Ó túmọ̀ sí pé nínú ọgọ́rùn-ún ènìyàn bí ìwọ, nǹkan bí ọgọ́ta ni ó ní àbájáde yìí. Kò sọ fún ọ ẹgbẹ́ tí ìwọ yóò wà.
Máa béèrè lọ́wọ́ wa nígbà gbogbo: ọgọ́rùn-ún ènìyàn bí èmi ní ọ̀nà wo? Ọjọ́ orí kan náà, ìpele kan náà, ìtọ́jú kan náà? Ìdáhùn náà ń yí ohun tí nọ́mbà náà túmọ̀ sí fún ọ padà.
Dókítà méjì ló kọ ọ́. A fi wé ìsọfúnni fún aláìsàn láti ọ̀dọ̀ National Cancer Institute ti Amẹ́ríkà àti Cancer Research UK. A túmọ̀ rẹ̀ láti inú káàdì èdè Gẹ̀ẹ́sì. A ń gbèrò kí dókítà tí ó gbọ́ Yorùbá ṣàyẹ̀wò ìtúmọ̀ yìí.