Kí ni ìpadàbọ̀ àìsàn túmọ̀ sí?
Ó túmọ̀ sí pé akàn náà ti padà lẹ́yìn àkókò tí a kò lè rí i. Ó lè padà sí ibi kan náà, tàbí sí ibòmíràn.
Ìpadàbọ̀ kì í ṣe ìkùnà, kì í ṣe tìrẹ tàbí tiwa. Kò sì túmọ̀ sí pé a ń bẹ̀rẹ̀ láti òfo. Béèrè ohun tí ó yípadà àti àwọn àyè tí ó wà báyìí, nítorí wọ́n sábà yàtọ̀ sí ti ìgbà àkọ́kọ́.
A túmọ̀ rẹ̀ láti inú káàdì èdè Gẹ̀ẹ́sì. A ń gbèrò kí dókítà tí ó gbọ́ Yorùbá ṣàyẹ̀wò ìtúmọ̀ yìí. Orísun: National Cancer Institute